Display Videos ( 251 - 275 of: 285 )
Pataki Adua(Yoruba)
2013-12-16
Ibanisoro yi da lori adua ati pataki re. Adua ni ohun ti o je oranyan fun Musulumi lati maa se nigbakiigba ti o ba nfe nkan, ki o si doju adua naa ko Olohun re, ki o mase pe elomiran ayafi Oun.
Agboye Esin Islam(Yoruba)
2013-12-15
Ibanisoro yi so nipa bi esin Islam se je esin ti o dasi igbesi aye eniyan patapata ti kii se nipa ohun ti o nse ninu mosalaasi nikan. Olubanisoro si menu ba itumo Islam, beenaani o so ewu ti o nbe nibi ki eniyan maa tele awon eniyan kan lori oro esin lai si eri.
Esin Islam ati Asa(Yoruba)
2013-12-15
Waasi yi so nipa asa ati esin Islam, olubanisoro pin asa si meji: eyi ti o dara ati eyi ti ko dara. Lehinnaa o so wipe esin Islam fi awon eniyan sile lori asa ti won nse ti o dara o si ko fun won nibi eyi ti ko dara wipe ki won fi sile.
2013-12-15
Olubanisoro se alaye bi ojise Olohun anabi Muhammad se je ike fun gbogbo aye, Olohun lo ojise naa lati se agbega fun awon iwa rere O si loo lati pa awon iwa buburu re. Olohun si da ojise re ni eniti o pe ni eda ati ni iwa.
Dida Ebi Po(Yoruba)
2013-12-15
Olubanisoro se alaye ohun ti o nje ebi, o si se alaye bakannaa bi o se ye ki eniyan maa da ebi re po. O tun se afikun anfaani ti o wa nibi ki eniyan maa da ebi po ati ijiya ti o wa nibi ki eniyan maa ja okun ibi pelu awon eri lati inu Al-kurani ati hadiisi.
Itoju Awon Obi Mejeeji(Yoruba)
2013-12-15
Waasi yi so nipa pataki sise daradara si awon obi mejeeji ati bi Olohun ti se e ni dandan fun omo eniyan, beeni o tun se alaye esan nla ti o wa nibi ki eniyan maa se itoju won ati aburu ti o wa nibi sise aidaa si won.
2013-12-15
Ibanisoro yi da lori sise Olohun ni okan soso ati awon ipin re meteeta. Olubanisoro si se alaye ni ekunrere eyi ti o se pataki julo ninu awon ipin wonyi ti opolopo Musulumi ni asiko yi si nse asise ti o fi oju han nibe.
Awon Ese Nla(Yoruba)
2013-11-27
Waasi yi da lori oro nipa awon ese nla. Olubanisoro si se alaye iyato ti o wa laarin awon ese nla ati kekere. O tun so nipa bi o ti se je ojuse Musulumi ki o mo wipe oranyan ni ki oun jinna si awon ese kekere ati nla.
Ijosin Ninu Islam(Yoruba)
2013-11-25
Ibanisoro yi da lori ijosin ati itumo re, oniwaasi so Pataki ki Musulumi se akiyesi awon majemu ijosin mejeeji: awon naa ni sise afomo ise fun Olohun ati sise ise ijosin naa ni ibamu pelu bi ojise Olohun ti se e. Lehinnaa ni o menu baa won oniran iran ijosin gege bii irun kiki aawe saka haj ati beebeelo. Ni ipari o so nipa awon nkan ti o maa nba ijosin je, eyi ti o sit obi ju ninu re naa ni ebo sise pelu Olohun.
Itoju Awon Arun ni Ilana Islam(Yoruba)
2013-11-25
Waasi yi so nipa awon ona iwosan ninu Islam. Oniwaasi so wipe awon aisan ti o maa nse awon eniyan pin si meji: aisan emin ati aisan ara. O si so wipe iso ti o dara julo nibi gbogbo arun naa ni iberu Olohun ati gbigbe ara le E. Lehinnaa, olubanisoro je ki a mo wipe kosi aisan ti ko ni itoju ayafi aisan ogbo. Bakannaa ni o menu ba die ninu awon nkan ti a fi maa nse itoju arun gege bii oyin, omi samsam ati beebeelo.
Ile Musulumi - 2(Yoruba)
2013-11-25
Olubanisoro so ninu apa keji waasi yi Pataki ki oko maa na owo le iyawo re lori, o si je ki a mo wipe ojuse ti Olohun se ni dandan fun un ni, Olohun si ti se adehun lati maa fi opolopo ropo ti o ba ti n na fun iyawo re. Bakanna ni oniwaasi so awon aleebu ti o wa lodo enikookan ninu oko ati iyawo ti o si gba won ni imoran lati fi won sile.
Ile Musulumi - 1(Yoruba)
2013-11-25
Ibanisoro yi da lori Ile Musulumi ati bi o se ye ki o ri. Olubanisoro so wipe ohun ti o se Pataki julo ki Musulumi mojuto ni ki o sa esa eni ti yoo fi se aya, ki obinrin Musulumi naa si sa esa eni ti yoo fi se oko. Ohun ti o si dara julo ki awon mejeeji wo naa ni esin lehinnaa iwa.
Igbagbo Ododo(Yoruba)
2013-11-25
Ibanisoro yi da lori igbagbo ninu Olohun ati alaye itumo re. Olubanisoro yi se alaye pupo lori itumo ohun ti o nje igbagbo, o si fi awon apeere laakaye ba awon eniyan soro pupo nibe nitoripe eleyi ni o ba awon ogooro eniyan ti won wa ni ijoko naa mu. Bakannaa ni o fi awon eri Al-kurani ati hadiisi se alaye.
2013-11-25
Oniwaasi so Pataki esin Islam o si je ki awon eniyan mo wipe gbigba esin Islam kiise mimoose enikan bikose aanu Olohun lori eni naa. Bakannaa o tun so iyato ti o wa laarin Islam ati awon esin yoku, ti o si so awon majemu ti o maa nje ki ise Musulumi di atewogba ni iwaju Olohun. Ni ipari o ba awon ti won gba Islam dupe, o fun won ni iro wipe Olohun maa nfi esin Islam pa awon ese ti eniyan ba ti se koja re, lehinnaa o so fun won bi o ti se je Pataki ki won jinna si ebo sise.
Oro Nipa Awon Alujannu - 2(Yoruba)
2013-11-18
Olubanisoro tun se alaye nipa bi awon alujannu se maa nlo awon eniyan ti won ba gbe ara won si ipo eniti won yoo maa ke pe ti won yoo si maa gbe aworan won wo lati fi so awon eniyan nu. Ni ipari, olubanisoro yi so nipa awon ona ti Musulumi yoo fi maa wa iso pelu Olohun ti alujannu ati awon eni esu ti won maa nlo won ko fi le ni agbara lori wa.
Oro Nipa Awon Alujannu - 1(Yoruba)
2013-11-18
Alaye ni ekunrere wa ninu ibanisoro yi nipa awon al-jannu. Bibe awon al-jannu ninu imo ikoko ti Musulumi gbodo ni igbagbo si ni, o nbe ninu awon al-jannu yi onigbagbo ododo o si nbe ninu won eni ti o ko ti Olohun ti o je keferi. Olubanisoro tun toka awon Musulumi si awon aaya ti ojise Olohun so fun wa wipe ki a maa fi wa iso.
2013-11-18
Ibanisoro yi se alaye ni ekunrere awon ola ti o n be fun osu Ramadan, ninu re si ni wipe Olohun daruko osu yi ninu Al-kurani ti ko si daruko osu miran leyin re. Ninu awon ola ti Olohun se fun osu yi ni wipe Olohun yoo pa ase wipe ki won si awon ilekun ogba idera Al-janna sile ti Yoo si pa ase pe ki won ti gbogbo awon ilekun ina ti won yoo si de gbogbo awon esu mole. Olubanisoro tun so ni ekunrere oro nipa ilana ojise Olohun lori bibere aawe.
2013-11-18
Ibanisoro yi da lori idajo Islam lori ki won da ina sun oku omo eniyan, Olubanisoro mu eri wa ninu hadiisi ojise Olohun lori wipe omo eniyan ni aponle leyin iku re bi o ti ni aponle nigbati o wa ni aye. Haraam ni idajo ki won da ina sun oku eniyan ninu Islam.
2013-11-18
Ibanisoro yi da lori idajo Islam lori ki won da ina sun oku omo eniyan, Olubanisoro mu eri wa ninu hadiisi ojise Olohun lori wipe omo eniyan ni aponle leyin iku re bi o ti ni aponle nigbati o wa ni aaye. Haraam ni idajo ki won da ina sun oku eniyan ninu Islam.
Igbaradi fun Osu Awe Ramadan - 2(Yoruba)
2013-11-18
Khutba yi so nipa oore ti o po ti Olohun se fun awa Musulumi pelu bi O ti se awon asiko kan ni adayanri fun awon ise oloore ti Musulumi yoo maa gba esan ti o po lori won. Ninu awon asiko naa si ni ojo Jimoh ati idameta oru igbeyin ati osu Ramadan.
Igbaradi fun Osu Awe Ramadan - 1(Yoruba)
2013-11-18
Khutba yi so nipa bi Musulumi yoo se mura sile fun osu Ramadan lati gba aawe nibe ati lati se awon naafila nibe. O so nipa bi awon eni isiwaju ninu esin se maa n pade osu Ramadan pelu idunnu ati ayo, ti won si maa n banuje ti o ba tan. Olubanisoro tun menu ba bi osu Shaaban se je osu imurasile ati yiye ara eni wo fun osu aawe Ramadan. O tun so nipa awon adadasile ti awon eniyan maa nse, o si so pe ki awon Musulumi jinna sii nitoripe esin ti di pipe ki ojise Olohun to fi aye sile.
Pataki Oro Omode ninu Islam(Yoruba)
2013-11-18
Khutba yi da lori oro nipa awon omode ati bi won ti se Pataki ni awujo. Oniwaasi fi oro yi se khutuba ni ibamu pelu ojo ti orile-ede Nigeria mu gege bii ojo awon ewe (omode). O si se alaye pupo nipa bi esin Islam ti se amojuto awon omode.
Amin Irole Aye - 8(Yoruba)
2013-11-17
Oniwaasi soro ni ipari waasi yi o si gba awon Musulumi ni iyanju lori ki won maa moju to esin Olohun bi o ti wule ki ibaje po to ni awujo, ki won si maa be Olohun ni opolopo, ki won jinna si ebo ati awon elebo. O si se adua ni ipari waasi naa fun gbogbo Musulumi.
Amin Irole Aye - 7(Yoruba)
2013-11-17
Oniwaasi soro nipa sisokale Anabi Isa omo Maryam, nigbati o ba de yoo pa agbelebu ati elede run, yoo si maa se idajo pelu deede ni ilana Anabi wa Muhammad.
Amin Irole Aye - 6(Yoruba)
2013-11-17
Oniwaasi soro nipa eranko kan ti Olohun yoo mu jade si awon eniyan ti yoo si maa ba awon eniyan soro gege bii okan ninu awon apeere irole aye ti o tobi. Bakannaa ni o so nipa yiyo oorun nibi ibuwo re, o si se afikun wipe ni asiko yi ko si anfaani fun ironupiwada fun enikankan mo.