Display Videos ( 201 - 225 of: 285 )
Ifeto si Ọmọ Bibi, Ifopin si Ọmọ Bibi, ati Oyun Sisẹ - 3
2014-06-02
Eyi ni abala ti o kun fun ibeere ati idahun, ti awọn ọrọ olowo-iye-biye si ti ibẹ yọ.
Ifeto si Ọmọ Bibi, Ifopin si Ọmọ Bibi, ati Oyun Sisẹ - 2
2014-06-02
Ni apa keji yi: (1) Itẹsiwaju alaye lori igbati irori fifi opin si ọmọ bibi bẹrẹ. (2) Ọrọ nipa oyun nini ati awọn idajọ ẹsin ti o rọ mọ ọ
Ifeto si Ọmọ Bibi, Ifopin si Ọmọ Bibi, ati Oyun Sisẹ -1
2014-06-02
Ibanisọrọ yi se alaye awọn koko wọnyi: (1) Iyatọ laarin ifeto sọmọ bibi ati ifopin sọmọ bibi. (2) Awọn ẹri pe Islam se wa lojukokoro lori ọmọ bibi. (3) Itan igba ti irori fifi opin si ọmọ bibi bẹrẹ.
Itọsọna fun Awọn ti nsise lara Ọkọ ati Awọn Onibara wọn - 3
2014-06-02
Ikilo ati ipeni si akiyesi fun awọn atọkọse lori awọn isesi buburu ti o wọpọ laarin wọn, eyi ti wọn nfi ọwọ yẹpẹrẹ mu, ti ibeere ati idahun si jẹ ohun ti wọn fi kadi eto nilẹ.
Itọsọna fun Awọn ti nsise lara Ọkọ ati Awọn Onibara wọn - 2
2014-06-02
Alaye lori Ojuse awọn atọkọse ati Imọran olowo iyebiye fun awọn atọkọse.
Itọsọna fun Awọn ti nsise lara Ọkọ ati Awọn Onibara wọn - 1
2014-06-02
Ninu apa kinni yi: (1) Itumọ Isẹ Ọwọ Sise pẹlu ẹri rẹ lati inu Alukuraani ati Sunnah. (2) Apejuwe ọkan-ọ-jọkan isẹ ọwọ ti Awọn Anọbi ti wọn ti rekọja lọ ti se lati fi wa jijẹ-mimu. (3) Ọrọ awọn onimimọ nipa iru isẹ ọwọ wo ni o dara julọ.
Alaye Itumo Aayah kẹtadinlaadọrun ninu Suuratul Bakọrah
2014-05-27
Itumọ aayah kẹtadinlaadọrun lati inu Suuratul Bakọrah eyi ti o da lori iroyin bi Ọlọhun Allah se se aranse fun Anọbi Isa ati bi awọn Yahuudi se tako igbedide Ojise Olohun Muhammad.
Ohun ti o ye ki Musulumi mo nipa Suufi
2014-05-27
Ibanisọrọ yii da lori awọn osuwọn tabi awọn ojupọnan ti Musulumi gbọdọ maa gbe isẹ ẹsin rẹ le ki o le jẹ atẹwọgba lọdọ Ọlọhun Allah.
Idajọ Tẹtẹ Tita Ninu Islam - 3
2014-05-27
Abala yi so nipa awon idahun si ibeere lorisirisi ti o wa lori akole ibanisoro yi.
Idajọ Tẹtẹ Tita Ninu Islam - 2
2014-05-27
Itẹsiwaju ẹkunrẹrẹ alaye lori orisirisi awọn ọna ti tẹtẹ pin si, ti olubanisọrọ si jẹ ki a mọ awọn isesi ti tẹtẹ wọ ati eyi ti tẹtẹ ko wọ, pelu diẹ ninu abala ibeere ati idahun.
Idajọ Tẹtẹ Tita Ninu Islam - 1
2014-05-27
Ibanisọrọ ni abala yii da lori awọn koko wọnyii: (i) Kinni Itumọ Tẹtẹ tita, (ii) Awọn ẹri ti o se Tẹtẹ Tita ni eewọ lati inu Alukuraani mimọ ati awọn Haadisi pẹlu apanupọ ọrọ awọn onimimọ, (iii) Awọn ewu ti nbẹ nibi tẹtẹ tita.
Idajọ Ibura laarin ọkọ ati iyawo (Al-Li’aanu)
2014-05-20
Ibanisọrọ yii da lori igbesẹ ti Islam fẹ ki Ọkọ iyawo gbe ti o ba se akiyesi pe iyawo rẹ nrin irinkurin, ti o si tun nse afihan bi Islam ti se idaabobo fun awọn obinrin kuro nibi abuku irọ Sina.
Idajo Sise Ise Ode ninu Islam - 4
2014-05-16
Awon ibeere waye ninu apa kerin yi ati idahun lekunrere lori won.
Idajo Sise Ise Ode ninu Islam - 3
2014-05-16
Ninu apa keta yi olubanisoro se alaye awon asise ti awon ode maa nse yala asise ti o ropo mo adiokan tabi eyi ti o ropo mo ise sise.
Idajo Sise Ise Ode ninu Islam - 2
2014-05-16
Ninu apa yi: (1) Oro nipa awon irinse ti eniyan fi le se ode. (2) Oro nipa awon eranko ti ko leto ki Musulumi je. (3) Die ninu awon eko sise ise ode.
Idajo Sise Ise Ode ninu Islam - 1
2014-05-16
Oro ni soki nipa ise ode ninu Islam, olubanisoro bere oro re pelu alaye bi esin Islam se dasi gbogbo igbesi aye omo eniyan ati awon eda miran ti ko si fi ibikankan sile lai dasi.
Ibasepo Ojise Olohun- ike ati ola Olohun ki o maa ba a- Pelu Awon Saabe re - 2
2014-05-15
Apa keji yi so nipa awon nkan wonyi: (1) Awon eko ti o dara julo ti o wa nibi ibasepo Ojise Olohun pelu awon Saabe re. (2) Sise awon Musulumi ni ojukokoro sibi kikose Ojise Olohun nibi awon iwa re fun oore aye ati orun.
Ibasepo Ojise Olohun- ike ati ola Olohun ki o maa ba a- Pelu Awon Saabe re - 1
2014-05-15
Waasi yi je idahun fun awon ibeere wonyi:
(1) Kinni paapaa itumo fiferan Ojise Olohun?
(2) Kinni idi ti Olohun fi royin Ojise Re pelu iwa rere nibi ti O ti so wipe: {Dajudaju ire (Anabi) ni o ni iwa ti o dara julo}.
(3) Tani eni ti o je dandan ki Musulumi mu ni awokose fun ara re lori gbogbo nkan?
Alaye Nipa Eto Isejoba Aye Titun ati Aburu ti o wa nibe fun Awa Musulumi
2014-04-26
Koko ohun ti ibanisoro yi da le lori ni: (1) Eto isejoba aye titun ni aburu ti yoo se fun awon ilu Musulumi, nibi eto oro-aje won ati awujo won. (2) Ohun ti oore aye ati ti orun wa nibe fun awa Musulumi ni ki a maa lo ofin Olohun nibi gbogbo ohun ti a ba n se.
AWON ONA TI ESU (SHATANI) FI MAA NDARI ENIYAN SI ONA ANU
2014-04-26
Waasi yi so nipa awon nkan pataki, ninu won ni: (1) Awon ona ti esu (shatani) maa ngba lati dari eniyan si ona anu. (2) Awon ohun ti esin Islam toka Musulumi si lati maa fi wa iso Olohun.
ORO NIPA AWON MALAIKA
2014-04-26
Oro waye ninu waasi yi lori itumo Malaika, ohun ti a gba lero pelu ki Musulumi ni igbagbo si Malaika, awon nkan ti Olohun fi sa won lesa ati wipe orisirisi ni won je.
IRIN AJO TI KO SE YE (IRIN AJO IKU)
2014-04-26
Oro nipa iku ati bi a se n we oku ni ilana esin Islam, pelu itoka si die ninu awon ohun ti o je dandan ki Musulumi ni igbagbo si lehin iku.
Ajosepo Laarin Awon Musulumi ati Awon ti Won Kiise Musulumi
2014-04-26
Waasi yi so nipa awon nkan kan, ninu won niyi: (1) Musulumi ni eni ti iwa daradara ti Islam pepe si ba han ni ara re. (2) Ninu ohun ti esin Islam pase re ni ki Musulumi maa se aponle gbogbo eniyan, eni ti o je Musulumi ati eni ti kiise Musulumi, ki o si maa dun won ninu.
ORO NIPA ESIN ISLAM NI ILE YORUBA
2014-04-26
Waasi yi so nipa awon asigboye esin ni odo awon iran Yoruba ti won da asa won po mo esin ti o si je wipe awon asa naa tako ohun ti esin Islam mu wa. Oniwaasi si menu ba awon asa ati ise kan ti o je wipe ebo sise ni won je sibesibe ti apa kan ninu awon Musulumi si mu won wo inu esin.
Wiwa Alubarika Eyi Ti O To Ati Eyi Ti Ko To - 2
2014-03-30
Alaye awon nkan ti awon eniyan fi nwa Alubarika ni ona eewo ati alaye awon nkan ti Alubarika wa nibe. Bakannaa ohun ti o fa asise awon eniyan nibi wiwa Alubarika, alaye si tun waye lori awon nkan eelo ti won so wipe Annabi- ike ati ola Olohun ki o maa ba a- lo nigba aye re, pelu mimu oro ti awon onimimo so nipa awon nkan wonyi wa.
Go to the Top