Display Videos ( 226 - 250 of: 285 )
Wiwa Alubarika Eyi Ti O To Ati Eyi Ti Ko To - 1
2014-03-30
Alaye lekunrere nipa itumo Alubarika ninu Ede larubawa ati ninu Shari’ah, ati oro nipa pataki Alubarika ati idajo wiwa Alubarika latara nkan tabi nibi nkan.
Esin Islam ni Ile Africa laarin Shariah ati Asa
2014-03-30
Ibanisoro yi da lori awon asa ti Islam fi ara mo ati awon eyi ti ko fi ara mo ni odo awon eya Yoruba ati die ninu awon eya miran ni ile alawo dudu (Africa). Awon olubanisoro mejeeji si mu awon apeere asa naa wa, bakannaa ni won menu ba pipe esin Islam.
Ojuse Imam ninu Islam - 3
2014-02-23
Apa keta ibanisoro naa so nipa idajo kiko masalaasi, bakannaa ni oro waye lori ohun ti o leto ki a se ninu mosalaasi ati awon ohun ti ko leto, leyinnaa ni idahun waye si awon ibeere.
Ojuse Imam ninu Islam - 2
2014-02-23
Apa keji ibanisoro naa, olubanisoro menu ba idajo wiwo masalaasi, alaye bi onirin-ajo yoo se maa ki irun re leyin onile ati idakeji, bakannaa idajo gbigba iwaju irun koja.
Ojuse Imam ninu Islam - 1
2014-02-23
Ibanisoro ti o so nipa awon majemu ti o gbodo pe si ara eni ti yoo ba wa ni ipo Imaam, yala Imaam ti inu irun ni tabi Imaam ti yoo je olori fun gbogbo Musulumi.
Adua ati Iranti Olohun ni ona ti o to - 2
2014-02-10
Olubanisoro tesiwaju pelu sise alaye awon asiko ti adua ma ngba, o si tun menuba awon nkan ti kii je ki adua gba, o wa se akotan ibanisoro re pelu awon nkan ti Yoruba ti ro po mo adua.
Adua ati Iranti Olohun ni ona ti o to - 1
2014-02-10
Ohun ti ibanisoro yi da le lori ni oro nipa adua, olubanisoro se alaye awon ohun ti a npe ni eko adua ti o tumo si awon nkan ti o maa nse okunfa gbigba adua.
Awon Asa ti o tako Sunna
2014-02-07
Olubanisọrọ se alaye awọn idajọ ẹsin ti o rọ mọ mima jẹ orukọ ẹlomiran ti o yatọ si baba ẹni, ati pipe apemọra nkan ti kii se ti ẹni (gẹgẹ bii imọ, dukia ati bẹẹ bẹẹ lọ). O si tun sọ nipa ewu ti o nbẹ nibi pipe musulumi kan ni keferi, ti wọn si kadi ibanisọrọ yii nilẹ pẹlu idahun ati ibeere.
Igbagbo Ninu Kadara
2014-02-07
Ibanisoro yi da lori alaye ni ekunrere nipa ohun ti a n pe ni kadara ati bi awon eniyan kan se sonu nitori re.
Taani Olohun- 2
2014-02-06
Olubanisọrọ tẹsiwaju ninu alaye awọn nkan ti o maa nse akoba fun Taoheed ninu iran Ẹbọ sise ati okunfa re, gẹgẹ bii Mima se ijọsin nibi saare oku, Gbigbẹ saare si inu mọsalaasi, Tita ẹjẹ silẹ fun nkan miran ti o yatọ si Ọlọhun Allah, Wiwa idaabobo tabi iranlọwọ lọdọ nkan miran ti o yatọ si Ọlọhun Allah. Ni akotan, wọn jẹ ki a mọ pe iru awọn nkan bayi le se akoba wiwọ Alujannah Musulumi.
Taani Olohun- 1
2014-02-06
Olubanisọrọ bẹrẹ pẹlu alaye orisirisi awọn alajẹ ede ti awọn eniyan fun Ọlọhun Allah, o si tun se alaye nipa Eni ti o tọ ki a maa jọsin fun laiwa orogun pẹlu Rẹ Ohun naa ni Ọlọhun .O si tun tẹsiwaju ninu sise alaye ohun ti wọn npe ni At-Taoheed (mimọ Ọlọhun lọkan soso) ati ẹka mẹtẹẹta ti o pin si.
Lilo Sunna Laarin Aseju ati Aseeto Lodo Awon Odo
2014-02-06
Ibanisọrọ yii da lori sise aseju tabi aseeto ninu ẹsin eyi ti o wọpọ laarin awọn ọdọ, ti olubanisọrọ si jẹ ki a mọ awọn okunfa rẹ gẹgẹ bii: 1-Aini imọ ẹsin ti o kun to, 2-Agbọye odi lori ẹsin, 3-lilero aburu si awọn onimimọ, 4-Igbarata ẹsin, 5- Sisọ gbogbo nkan di Bidi’ah, 6- fifun ilẹ mọni nibiti igbalaye wa ki gbolohun pe meji nibẹ. Ni igbẹyin, olubanisọrọ jẹ ki a mọ wipe gbigba Sunnah mu nikan ni o le yọ wa nibi aseju tabi aseeto.
Awon Nkan ti o nba Gbolohun Ijeri (La Ilaha Illa Allah) je
2014-02-01
Olubanisoro se alaye itumo gbolohun ijeri la ilaha illa Allah, o si tun so awon majemu ti o wa fun un ati awon nkan ti o maa nba gbolohun naa je.
Ojuse ati Eto Awon ti Oku fi Sile
2014-02-01
Oniwaasi so nipa awon eto ti Islam la kale fun awon ti oku fi sile, gege bii baba, iya, oko, iyawo, omokunrin, omobinrin ati beebeelo. O si tun menu ba awon asise ti o maa nwaye lori awon eto wonyi.
OWO- ELE (RIBA)
2014-02-01
Oniwaasi se alaye itumo aaya (276) ninu Suuratu Bakora, o si so ni ekunrere awon aburu ti o wa nibi ki eniyan maa gba owo ele.
Ojuse Odo Lori Atunse Awujo - 2
2014-01-13
Oniwaasi se afihan re wipe iyipada ko le waye laisi awon nkan wonyi: Alakoko: Agboye imo ijinle nipa esin Islam. Eleekeji: Wiwa awon imo ijinle ti awujo ni bukaata si. Eleeketa: Sise igbiyanju lati fi imo naa kede esin Islam.
Ojuse Odo Lori Atunse Awujo - 1
2014-01-13
Olubanisoro se alaye wipe imo nipa Olohun Allah ni eniyan maa fi n mo iyato laarin ohun ti o dara ati eyi ti ko dara, o si so wipe eniti o ba mo ohun ti o dara yato si eyi ti ko dara ni yoo le gbero ayipada ni awujo.
Oju-ona si Ogba Idera (Al-janna) - 2
2014-01-13
Oniwaasi se alaye ni abala yi wipe ti awon onimimo esin ba nso oro nipa awon ijo ti yoo la ti yoo ba ojise Olohun wo Al-janna itumo re ni wipe awon ti won ba ntele ilana ojise naa, kiise gbogbo eniti o ba npe ara re ni oni sunna, fun idi eyi oruko egbe ko tumo si nkankan bikose wipe ona kan lati pepe si oju ona Olohun.
Oju-ona si Ogba Idera (Al-janna) - 1
2014-01-13
Waasi yi da lori awon nkan ti yo maa je atona fun Musulumi losi ogba idera Al-janna, alakoko re ni adiokan ti o dara ti o jinna si ebo, eleekeji si ni ijosin ti o ni alaafia ti o wa ni ibamu pelu eyi ti ojise Olohun se.
Alaye Lori Sunna Ati Pataki Re Nibi Agboye Esin
2014-01-13
Olubanisoro se ni alaye lekunrere nkan ti won npe ni Sunna, o so pelu akori wipe odidi esin Islam ni Sunna atipe Sunna gan an ni esin Islam. O tesiwaju ninu alaye re wipe agboye Alkurani ko rorun fun Musulumi bikose latari Sunna, bee si ni Sunna je aayan ongbifo fun Alkurani Alaponle.
Ojuse Olori ati Awon ti won n dari ninu Islam - 2
2013-12-18
Eleyi ni apa keji ibanisoro naa, olubanisoro nso eyi ti o ku ninu awon majemu ti o ye ki o wa fun eniti a fe fi se olori ninu Islam.
Iyato ti o wa laarin Itoju Arun ni Ilana Islam ati Oogun Awon Elebo
2013-12-16
Oniwaasi so wipe awon nkan itoju arun ti Olohun se fun awa Musulumi po pupo ju ki a maa wa iranlowo nibi ohun ti o wa lodo awon keeferi ati elebo lo. O si so die ninu awon nkan iwosan naa, gege bi o ti so nipa awon eyi ti o je eewo fun Musulumi bii awon nkan ebo.
Ojuse Olori ati Awon ti won n dari ninu Islam - 1
2013-12-16
Waasi yi so nipa bi o ti je wipe esin Islam menu ba gbogbo nkan patapata ti o fi de ibi eko bi a ti se n to tabi ya igbe, bawo ni Islam kose wa ni so nipa eto bi a se ndari ilu ati bi a se nse ijoba.
Kinni Idi ti Olohun fi da wa ?
2013-12-16
Ibanisoro yi da lori idahun fun ibeere ti o n so pe: kinni idi ti Olohun fi da awa erusin Re? Oniwaasi si dahun ni kukuru wipe nitori ijosin ni Olohun fi da awa eniyan ati alijonnu. Oju ona kan soso ti a si fi le sin Olohun naa ni esin Islam.
Pataki Imo ati Ojuse Awon Onimimo tele ati nisisiyi ni Nigeria
2013-12-16
Koko oro inu waasi yi ni alaye lori pataki imo ati pataki awon onimimo, bakannaa ni bi o se se pataki to ki apa kan ninu awon Musulumi gbiyanju lati wa imo leyinnaa ki won se awon eniyan ni anfaani pelu imo won fun atunse awujo.
Go to the Top