Display Videos ( 276 - 285 of: 285 )
Amin Irole Aye - 5
2013-11-17
Oniwaasi so ninu ibanisoro yi nipa awon apeere kekere ninu awon apeere irole aye, gege bii ki awon eniyan maa se aponle okunrin kan nitori iberu aburu ise owo re. Leyinnaa o menu ba die ninu awon apeere irole aye ti o tobi, o si ka hadiisi ti Udhaefa gba wa lati odo ojise Olohun ti o so nipa awon apeere irole aye ti o tobi. Oniwaasi tun so nipa Dajjal gege bii okan ti o se Pataki ninu awon apeere irole aye ti o tobi.
Amin Irole Aye - 4
2013-11-17
Oniwaasi so ninu ibanisoro yi nipa awon apeere kekere ninu awon apeere irole aye, o so nipa wiwa imo nitori oro aye, ati bi okunrin yoo se maa tele ase iyawo re ti yoo si maa se aburu si iya re, bakannaa bi awon eniyan yoo se maa pariwo ninu mosalaasi fun ohun ti kiise iranti Olohun.
Amin Irole Aye - 3
2013-11-17
Oniwaasi so ninu ibanisoro yi nipa awon apeere kekere ninu awon apeere irole aye, o so nipa bi onka awon obinrin yoo se po ni awujo, bakannaa ni ki awon eniyan maa se afiti nkan si odo eni ti kii se eni ti o leto si i.
Amin Irole Aye - 2
2013-11-17
Oniwaasi so ninu ibanisoro yi nipa awon apeere kekere ninu awon apeere irole aye, o si menu ba bi o se je wipe awon ti won je onimimo nipa oro Olohun yoo tan ni ori ile, ti iwa agbere yoo po, bakannaa ni oti mimu ati beebeelo.
Amin Irole Aye - 1
2013-11-17
Ibanisoro yi so nipa die ninu awon apeere ti a o fi maa mo nigbati opin aye ba n sunmo. Oniwaasi so ni ibere oro yi wipe gbigbe dide Anabi wa Muhammad je okan ninu awon apeere irole aye. Bakannaa ni oro wa lori sisokale Anabi Isa omo Maryam gege bii okan ninu awon apeere irole aye. Eyi si je akoko ninu ibanisoro yi ti o je sise-ntele.
Ola ti o wa fun Eni ti o ba mo Olohun lokan
2013-11-13
Ibanisoro yi je ki a mo Pataki ki Musulumi mo Olohun re ni okan soso ki o si doju ijosin ko Olohun naa. Mimo Olohun ni okan (Taoheed) ni ipile esin, ohun si ni ohun ti o ye ki Musulumi moju to julo.
Sise Daadaa si Awon Obi Mejeeji ati Ikilo lori sise aburu si won
2013-11-12
Sise daadaa si awon obi je ojuse Pataki ti Olohun pa omo ni ase re leyin ti o pase wipe ko gbodo josin fun nkan miran yato si Oun Olohun. Eleyi ni ohun ti ibanisoro yi da lelori, olubanisoro si mu awon apejuwe lori oore ti o wa ninu ki eniyan maa se daadaa si awon obi ati aburu ti o wa nibi ki eniyan maa se aidaa si won.
Eko nipa Odun Itunu Aawe
2013-11-10
Olohun se ipari aawe ati ojo kewa osu Dhul-hijja ni odun fun awa Musulumi. Ibani soro yi n so nipa awon eko ti Islam ko wa nipa odun aawe. Ninu re ni ki Musulumi wo aso ti o dara ti o si wuyi ni ojo odun lati gbe ojo yi laruge. Ojise Olohun si pase wipe ki gbogbo Musulumi jade lo si aaye ikirun fun odun yii.
Gbigba Kadara gbo
2013-11-08
Akole yi so nipa bi o ti se je ojuse Musulumi ki o so enu aala Olohun nigba ti o ba n wa arisiki, ki o ma gba ona haraam ti Olohun ko fe lati fi wa oro. Ki o ma fi ibinu Olohun wa iyonu awon eniyan.
Pataki titele Sunna Anobi Muhammad
2013-04-24
Oludanileko ninu eto yii soro nipa bi o ti se Pataki fun Musulumi ki o maa tele Sunna Anobi wa Muhammad
Go to the Top