Display Videos ( 176 - 200 of: 285 )
Taani Aafa (Alufa)? -2
2015-03-07
Ni abala yii, ọrọ waye lori awọn ohun isami Aafa ni ọdọ awọn ẹya Yoruba pẹlu awọn oniranran apẹrẹ ẹni ti awọn Yoruba ka kun onimimọ.
Taani Aafa (Alufa)? -1
2015-03-07
Ninu idanilẹkọ yii ọrọ waye nipa itumọ Aafa tabi Alufa ninu ede ati ni oniranran ọna ti a fi le gbọ itumọ rẹ ye, pẹlu itọka si awọn amin ti a fi le da Aafa mọ ni awujọ.
Nini Igbagbọ si Ọjọ Idajọ - 3
2015-03-07
Ninu apa yii alaye diẹ waye nipa awọn iroyin Alujannah ati Ina, ti ibeere ati idahun si jẹ ohun ti wọn fi kadi idanilẹkọ nilẹ.
Nini Igbagbọ si Ọjọ Idajọ - 2
2015-03-07
Alaye tẹsiwaju lori awọn isẹlẹ ti yoo sẹlẹ lẹyin iku pẹlu mimẹnuba oniranran ipo ọmọniyan nigbati wọn ba gbe sinu saare.
Nini Igbagbọ si Ọjọ Idajọ - 1
2015-03-07
Ninu apa yii ọrọ waye lori awọn ẹri lati inu Alukuraani ti o ntọka si ododo sisẹlẹ ọjọ igbende Alukiyaamọ ati bi o se jẹ dandan ki a ni igbagbọ si ọjọ naa, ti olubanisọrọ si sọ diẹ ninu awọn amin isunmọ ọjọ yii pẹlu awon ẹri ti o gbee nilẹ.
Ọla ati Ipo ti o wa fun Awọn Saabe Ojisẹ Ọlọhun (Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a)- 3
2015-03-07
Awọn imọran fun gbogbo Musulumi lori bi igbiyanju si oju ọna ẹsin yoo se maa tẹsiwaju ni ohun ti wọn fi kadi eto nilẹ.
Ọla ati Ipo ti o wa fun Awọn Saabe Ojisẹ Ọlọhun (Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a)- 2
2015-03-07
Ọrọ waye ninu apa keji yii lori: (1) Iwọ ti o yẹ ki awa Musulumi maa pe fun awọn saabe Anabi. (2) Awọn ẹri ti o fi ẹsẹ mulẹ lori wipe ko si ede aiyede laarin awọn ara ile Anabi ati awọn Saabe yoku.
Ọla ati Ipo ti o wa fun Awọn Saabe Ojisẹ Ọlọhun (Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a)- 1
2015-03-07
Awọn ohun ti o waye ninu apa yii: (1) Itumọ Saabe ninu ede larubawa ati wipe taani awọn Saabe gẹgẹ bi awọn onimimọ se se apejuwe wọn. (2) Ipo ati ọla ti nbẹ fun awọn Saabe pẹlu ẹri rẹ lati inu Sunna.
Idan ati Asasi -3
2015-03-07
Idajọ lilọ si ọdọ awọn opidan pẹlu awọn ibeere ati idahun olowo iye biye.
Idan ati Asasi -2
2015-03-07
Idajọ idan pẹlu awọn ẹri lati inu Alukuraani ati Sunna, awọn ijiya ti nbẹ fun opidan ati awọn adua isọ kuro nibi aburu awọn opidan.
Idan ati Asasi -1
2015-03-07
Ni apa yii, alaye waye nipa ipilẹ idan sise pẹlu iyatọ ti o nbẹ laarin oogun lilo ati idan.
Awọn Okunfa Lilekun ati Didinku Igbagbọ-4
2015-02-08
Abala yii jẹ idahun si awọn ibeere olowo-iye-biye ti o waye ni ipari idanilẹkọ naa.
Awọn Okunfa Lilekun ati Didinku Igbagbọ-3
2015-02-08
Abala yii se ifọsiwẹwẹ awọn nkan ti o maa nse alekun igbagbọ musulumi pẹlu alaye rẹ.
Awọn Okunfa Lilekun ati Didinku Igbagbọ-2
2015-02-08
Abala yii se alaye wipe Igbagbọ maa nlekun, o si maa ndinku pẹlu awọn ẹri lati inu Alukuraani ati Hadisi.
Awọn Okunfa Lilekun ati Didinku Igbagbọ-1
2015-02-08
Idanilẹkọ yii bẹrẹ pẹlu sisọ itumọ igbagbọ pẹlu orisi ọna ti a le gbọ ọ ye si, yala ninu adisọkan ni, tabi wiwi jade ni ẹnu, tabi fifi sisẹ se.
Ojuse ati Ẹtọ Awọn Obinrin Musulumi ni Awujọ -2
2014-11-28
Eleyi ni afikun alaye lori awọn ojuse obinrin musulumi, ti alaye nipa awọn ẹtọ obinrin musulumi si jẹ ohun ti wọn fi tẹle.
Ojuse ati Ẹtọ Awọn Obinrin Musulumi ni Awujọ -1
2014-11-28
Idanilẹkọ yii da lori awọn koko wọnyii: (i) Sise alaye ipo ti awujọ gbe obinrin si pẹlu afiwe rẹ si ipo ti Islam gbe obinrin si. (ii) Sise ni alaye abala diẹ ninu awọn ojuse obinrin musulumi si gbogbo awọn agbegbe ti o nii se pẹlu igbesi aye won.
Idẹkun Wahala laarin Lọkọ-Laya -3
2014-11-18
Eyi ni abala idahun si awọn ibeere ti o jẹyọ lati ibi idanilẹkọ yii.
Idẹkun Wahala laarin Lọkọ-Laya -2
2014-11-18
Abala yii sọ nipa awọn ọna mẹrin ti ede-aiyede ma ngba wa laarin lọkọ-laya, oludanilẹkọ si tun se alaye awọn igbesẹ ti Islam fẹ ki a gbe nigbati ede-aiyede ba waye laarin lọkọ-laya.
Idẹkun Wahala laarin Lọkọ-Laya -1
2014-11-18
Alaye ni abala akọkọ Idanilẹkọ yii da lori awọn koko wọnyii: (i) Sisọ nipa pataki ati anfaani ti o wa nibi igbeyawo, (ii) Sise alaye awọn ojuse lati ọdọ ọkọ si iyawo rẹ, bẹẹ naa ni awọn ojuse lati ọdọ iyawo si ọkọ rẹ, (iii) Sise apejuwe oniranran ede-aiyede laarin lọkọ-laya.
Iha ti Islam ko si Imo- 3
2014-11-18
Abala yii ni o gbẹyin idanilẹkọ yii ti o si kun kẹkẹ fun awọn ibeere pẹlu awọn idahun wọn.
Iha ti Islam ko si Imo- 2
2014-11-18
Oro waye ni apa yii lori awọn orisirisi ẹkọ ti o yẹ ki a ni akolekan rẹ lori imọ tabi ẹkọ ti a nwa, ti abala akọkọ ninu ibeere ati idahun si gbẹyin rẹ .
Iha ti Islam ko si Imo- 1
2014-11-18
Koko idanileko yii: (1) Awọn ẹsẹ Alukuraani ti nsọ nipa pataki Imọ ati awọn Onimimọ. (2) Alaye iru awọn imọ ti o le se wa ni anfaani ati eyi ti ko le mu anfaani kankan wa fun wa. (3) pataki wiwa imọ ẹsin pẹlu awọn nkan ti a gbọdọ sọ ni oju ọna imọ wiwa.
Pataki Alukuraani ati Titobi Rẹ - 2
2014-06-02
Alaye awọn nkan ti o le ran Musulumi lọwọ lati jẹ Olumọ Alukuraani pelu ibeere ati idahun.
Pataki Alukuraani ati Titobi Rẹ - 1
2014-06-02
Ninu apa kinni yi: (1) Oro nipa awọn orukọ, iroyin ati awọn ẹwa ti Ọlọhun fi se iroyin Alukuraani. (2) Awọn ọla ti nbẹ fun Alukuraani. (3) Awọn ẹkọ ti o wa fun kika Alukuraani ati ọla ti nbẹ fun Olumọ Alukuraani.
Go to the Top